Àwọn Domain
Fún onírúurú ìdí tó jẹ mọ́ trademark WordPress wa, a béèrè pé tí o bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìkànnì nípa WordPress tàbí tó jẹ mọ́ ọn pé má lo “WordPress” nínú orúkọ orúkọ ìkànnì. Gbìyànjú “wp” dípò, tàbí àyípadà mìíràn. Àwa kì í ṣe amòfin, ṣùgbọ́n àwọn amòfin tó dára gan-an sọ fún wa pé a gbọ́dọ̀ ṣe èyí láti pa trademark wa mọ́. Bákan náà, ọ̀pọ̀ olùlò ti sọ fún wa pé ó ń dàrú mọ́ wọn lójú.
Tí o bá ti ní orúkọ ìkànnì tó ní “WordPress” nínú rẹ̀, darí rẹ̀ sí ẹ̀dà “wp” rẹ̀ dára, níwọ̀n ìgbà tí èyí tí àwọn olùlò ń rí tí o sì ń gbé lárugẹ kò ní “WordPress” nínú, àti ní ìgbà pípẹ́ o yẹ kí o gbé gbígbé èyí àtijọ́ lọ sí Foundation yẹ̀ wò.
“WordPress” nínú àwọn sub-orúkọ ìkànnì dára, bíi wordpress.example.com, orúkọ ìkànnì top-level nìkan ni ó kàn wá lẹ́nu.
A ti sọ èyí fún ẹnikẹ́ni tó bá ti béèrè lọ́wọ́ wa rí, a kàn fẹ́ kí ó di ti gbogbo ènìyàn kí àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i lè mọ̀ nípa ìlànà yìí.
Tí o bá rí àwọn orúkọ ìkànnì mìíràn tó ń lo WordPress, tí wọn kì í sì í ṣe WordPress.com, WordPress.net, WordPress.org, WordPress.tv, tàbí WordPressFoundation.org, a kò gbà wọ́n láàyè. O yẹ kí o kàn sí olùní wọn kí o sì tọ́ka sí ojú ìwé yìí. A máa ń rí èyí ní ìgbà tó pọ̀ jù lórí àwọn spammy ìkànnì tó ń pín àwọn plugin àti theme tó ní malware. Nípa pípè wọ́n síta, ò ń ran lọ́wọ́ láti dáàbò bo ìdúróṣinṣin iṣẹ́ àkànṣe náà.